1 Chronicles 7
World English Bible (en) → Yoruba Contemporary Bible (Biblica) (yo)
- 1
Àwọn ọmọ Isakari:
- 2
Àwọn ọmọ Tola:
- 3
Àwọn ọmọ, Ussi:
- 4
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (36,000) tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.
- 5
Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádọ́rin (87,000) ni gbogbo rẹ̀.
- 6
Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini:
- 7
Àwọn ọmọ Bela:
- 8
Àwọn ọmọ Bekeri:
- 9
Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó lé nígba (20,200) ọkùnrin alágbára.
- 10
Ọmọ Jediaeli:
- 11
Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba (17,200) akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.
- 12
Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.
- 13
Àwọn ọmọ Naftali:
- 14
Àwọn ìran ọmọ Manase:
- 15
Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
- 16
Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.
- 17
Ọmọ Ulamu:
- 18
Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.
- 19
Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́:
- 20
Àwọn ìran ọmọ Efraimu:
- 21
Sabadi ọmọ, rẹ̀,
- 22
Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
- 23
Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.
- 24
Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.
- 25
Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀,
- 26
Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀,
- 27
Nuni ọmọ rẹ̀
- 28
Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.
- 29
Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.
- 30
Àwọn ọmọ Aṣeri:
- 31
Àwọn ọmọ Beriah:
- 32
Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.
- 33
Àwọn ọmọ Jafileti:
- 34
Àwọn ọmọ Ṣomeri:
- 35
Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu
- 36
Àwọn ọmọ Sofahi:
- 37
Beseri, Hodi, Ṣamma, Ṣilisa, Itrani àti Bera.
- 38
Àwọn ọmọ Jeteri:
- 39
Àwọn ọmọ Ulla:
- 40
Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin.