1 Chronicles 6
World English Bible (en) → Yoruba Contemporary Bible (Biblica) (yo)
- 1
Àwọn ọmọ Lefi:
- 2
Àwọn ọmọ Kohati:
- 3
Àwọn ọmọ Amramu:
- 4
Eleasari jẹ́ baba Finehasi,
- 5
Abiṣua baba Bukki,
- 6
Ussi baba Serahiah,
- 7
Meraioti baba Amariah,
- 8
Ahitubu baba Sadoku,
- 9
Ahimasi baba Asariah,
- 10
Johanani baba Asariah.
- 11
Asariah baba Amariah
- 12
Ahitubu baba Sadoku.
- 13
Ṣallumu baba Hilkiah,
- 14
Asariah baba Seraiah,
- 15
A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.
- 16
Àwọn ọmọ Lefi:
- 17
Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:
- 18
Àwọn ọmọ Kohati:
- 19
Àwọn ọmọ Merari:
- 20
Ti Gerṣoni:
- 21
Joah ọmọkùnrin rẹ̀,
- 22
Àwọn ìran ọmọ Kohati:
- 23
Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,
- 24
Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,
- 25
Àwọn ìran ọmọ Elkana:
- 26
Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀
- 27
Eliabu ọmọ rẹ̀,
- 28
Àwọn ọmọ Samuẹli:
- 29
Àwọn ìran ọmọ Merari:
- 30
Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀
- 31
Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
- 32
Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
- 33
Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn.
- 34
ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu,
- 35
ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,
- 36
ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli,
- 37
ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,
- 38
ọmọ Isari, ọmọ Kohati,
- 39
Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:
- 40
ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,
- 41
ọmọ Etini,
- 42
ọmọ Etani, ọmọ Simma,
- 43
ọmọ Jahati,
- 44
láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:
- 45
ọmọ Haṣabiah,
- 46
ọmọ Amisi, ọmọ Bani,
- 47
ọmọ Mahili,
- 48
Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
- 49
Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
- 50
Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:
- 51
Bukki ọmọ rẹ̀,
- 52
Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,
- 53
Sadoku ọmọ rẹ̀
- 54
Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
- 55
A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
- 56
Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne.
- 57
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa,
- 58
Hileni, Debiri,
- 59
Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
- 60
Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 61
Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.
- 62
Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.
- 63
Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
- 64
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 65
Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
- 66
Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
- 67
Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri
- 68
Jokimeamu, Beti-Horoni.
- 69
Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 70
Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.
- 71
Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí.
- 72
Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
- 73
Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 74
Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
- 75
Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 76
Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
- 77
Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí.
- 78
Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,
- 79
Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
- 80
Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,
- 81
Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.