Psalms 54
World English Bible (en) → Yoruba Contemporary Bible (Biblica) (yo)
Key words
- 1
Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ.
- 2
Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
- 3
Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
- 4
Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
- 5
Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
- 6
Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa, nítorí tí ó dára.
- 7
Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.