Psalms 124
World English Bible (en) → Yoruba Contemporary Bible (Biblica) (yo)
Key words
- 1
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
- 2
ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
- 3
nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
- 4
nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
- 5
nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.
- 6
Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
- 7
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.
- 8
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.